Osun Osogbo Shrine Porn Video: Wo gb mj lrn dn mj t ojb Osun Osogbo ti

14 Owewe 2020

Ìgbà tí a ṣe àfíkun gbẹ̀yìn 16 Owewe 2020

Ni aipẹ yii ni iroyin kan jade pe awọn ọdọ kan lọ ṣe aṣemaṣe ni ojubọ Oṣun oṣogbo ni ilu Osogbo.

Ariwo gbaye kan lori rẹ nitori lara awọn oriṣa to gbajugbaja julọ ni ilẹ Yoruba ni Ọṣun wa koda ilu mẹta ọtọọtọ ni wọn ti n ṣe ọdun ọṣun oṣogbo - ilu Osogbo, ilu Ifẹ ati ilu Ifaki Ekiti.

Njẹ ẹ mọ pe laarin ọdun mej,i igbakeji niyi ti ariwo kotọ yoo maa sọ eleyi ti yoo rọ mọ ojubọ Ọṣun tabi oriṣa naa funrarẹ.

Ta lo ji Ọsun gbe?

Ni ọdun 2019 ni iroyin jade sita pe ko si oriṣa ọṣun ni ojubọ rẹ mọ atipe awọn kan ti taa fun ẹgbẹlẹgbẹ owo dọla ilẹ Amẹrika.

Ẹni to jẹ Baba Ọṣun tẹlẹ, Alagba Ọlayiwla Adigun ṣalaye pe kabiyesi Ataọja ti ilu Oṣogbo ti ta oriṣa ọṣun fun awọn are kan ati pe igba ti wọn fẹ gbee jade kuro lorilẹede Naijiria ni Ọṣun wa wuwo ti ko ṣe e gbe mọ ti o fi wa yọ si ọkan lara wọn pe ki wọn da oun pada sọdọ awọn to ni oun bi wọn ko ba fẹ ri pipọn oju oun.

Amọṣa nigba ti BBC gbe ọrọ naa tọ Kabiyesi Ataọja nigba naa, baba ni ko soun to jọọ ati pe ija lo de torin dowe.

Kabiyesi Ataọja no oun ko ta oriṣa Ọṣun ṣẹngẹṣẹ, lile ti igbimọ Atasja le Alagba Ọlayiwla Adigun kuro nipo Baba Ọṣun lo mu ki o gbarata sọ ọrọ odi naa jade.

Titi di bi a ṣe n sọrọ yii alagba Ọlayiwla Adigun ṣi n duro lori pe oriṣa Ọṣun ko si ni ojubọ rẹ ms bayii, bẹẹni baba Ataọja pẹlu n faake kọri pe oun ko ta oriṣa Ọṣun.

Àkọlé fídíò,

'Búrẹ́dì tí wọn ó fi jẹ ẹ̀wà ni wọ́n lọ rà ni wọ́n pàdé ikú gbígbóná'

Àkọlé fídíò,

Osun Osogbo: Àtáója ní káwọn èèyàn má a bọ̀ wá bọ Ọ̀ṣun lónìí, torí kò ṣe é jígbé,

Ki lo fa 'Blue film' lojubọ Ọṣun?

Nigba ti awọn araalu ṣẹṣẹ n simi lori awuyewuye yii, ni iroyin kan tun jade lọsẹ yii pe arakunrinkan ti orukọ rẹ n jẹ Tobilọba Jọlaosho lọ ya sinima onibalopọ ti a mọ si 'Blue film' lojubọ naa.

Iroyin yii ka gbogbo aye laya to si mu ki ọpọ o maa ṣe haa hin, ki ree?

Titi di bi a ṣe n sọrọ yii, Tobilọba ti foju ba ile ẹjọ o, koda o ti kawọpọnyin wi fun adajọ pe oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun rara.

Àkọlé fídíò,

'Ọ̀nà àtijẹ kan ṣoṣo táa ní ni Màálù àwọn Fúlàní ti bàjẹ́'

Mi ò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí ẹ fi kàn mí pé mo ya "Blue Film" nínú igbó Osun Osogbo - Jolaosho TBlak

Tobiloba Jolaosho ti ọpọ mọ si King Tblak ti sọ̀rọ̀ niwaju ile ẹjọ pe oun ko jẹbi rara nipa ẹsun ti wọn fi kan an pe o lọ ya fiimu ibalopọ ninu igbo Osun Osogbo.

Ile ẹjọ Majisireeti kan niluu Osogbo tii ṣe olu ilu ipinlẹ Osun ti pe Tobiloba Jolaosho atawọn marun mii ti wọn jọ wa latimọle ọlọpaa ki wọn wa jẹ́jọ́.

Ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn ọhun to gbajugbaja lori ayelujara pẹlu orukọ to n lo, "TBlak" ni wọn fi ẹsun kan pe o dan nkan eewọ wo ninu igbo Osun Osogbo nibi to ti lọ ya fiimu ibalopọ pẹlu obinrin kan ni ihoho.

Àkọlé fídíò,

Ọmọ méjì ò sọnù nínú àgbàrá òjò o! Ọ̀tọ̀ lọ̀rọ̀ táa ń pè yín sí - Aráa Ketu

Iroyin fihan pe ọwọ ọlọpaa tẹ Jolaosho nigba ti awọn agbaagba ẹlẹsin ibilẹ fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa leti.

Awọn ti wọn jọ kawọ pọnyin rojọ nileẹjọ Majisireeti ni pẹlu Jolaosho ni Ladiva Aije, Juliet Semion, Ahmed Olasunkanmi, Eritosin ati Tunde Jimoh ti wọn si fi ẹsun mẹjọ kan wọn to rọ mọ yiya fiimu ibalopọ ninu igbo Osun Osogbo.

Adajọ olupẹjọ, John Idoko fi ẹsun kan wọn pe wọn lọ yaworan nibẹ pẹlu awọn ọdọbinrin to fẹrẹẹ tu sihoho ti wọn si fi sita lori ayelujara eyi to lodi si igbagbọ ninu ẹsin ibilẹ ti wọn n ṣe ni Osun.

Ẹwẹ, TBlak ati awọn afurasi to ku ni awọn ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn.

Ile ẹjọ si ti sun igbẹjọ naa siwaju di ọjọ kẹtadinlogun oṣu kẹsan ọdun 2020.

Ọmọkunrin kan, Tobiloba Jolaosho, ni awọn ọlọpaa ti mu nitori pe o ya fidio ibalopọ ninu igbo Osun Osogbo, to si tun fi fidio naa sori ayelujara.

Oṣere sinma ibalopọ, ti awọn elede Gẹẹsi n pe ni porn tabi blue film, ni Jolaosho, ti inagijẹ rẹ n jẹ King Tblak HOC.

Iroyin sọ pe ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ ẹlẹsin ibilẹ nipinlẹ Osun lo fi ọrọ to ileeṣẹ ọlọpaa l'eti pe, oun ri Jolaosho ninu fidio naa to n hu iwa ibajẹ ninu igbo ọhun. Eyi to le da alaafia ilu ru.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Osun, Opalola Yemisi sọ fun BBC pe wọn o gbe Jolaosho lọ sile ẹjọ, ti iwadii ba pari.

Àkọlé fídíò,

Tóò bá fún ọkùnrinn lóúnjẹ́ tóo tẹ́ kiní yẹn sílẹ̀ fún un dáadáa... - Yinka TNT

Wọn fi ẹsun kan pe niṣe lo mura bi abọriṣa Osun, ti oun ati ọmọbinrin kan to wa ni ihoho si jọ ni ibalopọ ninu ojubọ naa, l'oṣu Keje, ọdun 2020.

Oriṣiriṣi fidio ibalopọ naa lo kun ori ayelujara Twitter ọmọkunrin ọhun, to ti ni ololufẹ to le ni ẹgbẹrun mẹrindinlọgbọn to n tẹle e lori ayelujara.

O si tun ni itakun agbaye ti awọn eeyan ti ma n san owo lati wo awọn fidio naa.

Nigba to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun BBC Yoruba, Araba ilu Osogbo, to tun jẹ ọkan lara awọn alamojuto ẹsin ibilẹ nilẹ Yoruba, Oloye Ifayemi Elebuibon, sọ pe niṣe ni ọmọkunrin naa fi kele ati ọpẹlẹ kọrun, to si lọ ba awọn obinrin ṣe aṣemọṣe.

"Ao mọ nkan to kọlu ọmọkunrin naa. Bi igba ti eeyan fẹ ẹ da ẹrẹ si ibi ti a pe ni ibi mimọ ni nkan to ṣe.

"Ibi ti gbogbo eeyan ti n wa kaakiri agbaye lati ṣe tutu, lo lọ ọ mu abawọn ba."

Elebuibon sọ pe ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ti tẹ ọmọkunrin naa.

"O ti ba aye ara rẹ jẹ, ori rẹ ti gbalẹ baun, nitori iwa to hu yii."

Àkọlé fídíò,

Ìtàn ọ̀rẹ́ tó fi ògùn gba ọkọ ọ̀rẹ́ rẹ̀ ni Akomolede BBC Yorùbá fẹ́ kọ́ wa lònìí

Bakan naa ni o fi kun pe nigba ti ileeṣẹ ọlọpaa ba pari iwadii wọn lori ẹsun ti wọn fi kan Jolaosho, ni awọn ẹlẹsin ibilẹ yoo to o da sẹria to tọ fun.

Oriṣa pataki ni Osun jẹ nilẹ Yoruba, kaakiri agbaye si ni awọn eeyan ti ma n wa fun ayẹyẹ ọdun Osun Osogbo lọdọọdun.

BBC gbiyanju lati ba Jolaosho sọrọ lori foonu nipasẹ numba kan to fi si ori ayelujara Twitter rẹ, ṣugbọn igbiyanju wa ko so eso rere.

ncG1vNJzZmivp6x7o67CZ5qopV%2BuvLPBwZpmmp6inriieZRtaG1tYWmD